ANOTHER WAY TO LEARN YORUBA ALPHABETS

Who say there is no learning, why we having fun to the fullest eh! abeg pack...

A - Alaafia fun o.
B - Buburu kan ki yoo subu lu o.
D - Dugbedugbe ibanuje ko ni ja le o l'ori.
E - Ebi o ni pa o nibi ti odun yi ku si
E - Ekun, ose ko ni je tire.
F - Funfun aye re ko ni dibaje.
G - Gunnungun ki ku l'ewe, wa dagba d'arugbo.
GB - Gbogbo idawole re a y'ori si rere.

H -Hausa,Yoruba,Ibo,gbogbo eya ati eniyan kaakiri agbaye ni yo koju si o se o loore.
I - Iwaju, iwaju l'opa ebiti re yo ma re si.
J - Jijade re, wiwole re, o o ni k'agbako.
K - Kukuru abi giga, osi ati ise ko ni je tire.
L - Loniloni wa r'aanu gba.
M - Monamona ati ara Olorun yoo tu awon ota re ka.
N - Naira, Euro, Dollar, Pound,Yen,Yuan,gbogbo owo ati oro kaakiri agbaye pelu omo alalubarika ati alaafia yoo mu o l'ore, won o si fi ile re se ibugbe.
O - Ojurere ati aanu yoo ma to o leyin ni ojo aye re gbogbo.
O - Ojo ola re a dara.
P - Panpe aye o ni mu o t'omotomo.
R - Rere ni agogo aye re o ma lu nigbagbogbo.
S - Suuru pelu itelorun ninu oro at'alaafia yoo ba o kale.
S - Sugbon ati abawon aye re ti poora loni.
T - Tomotomo, t'ebitebi, t'iletile o ni d'ero eyin.
U - U ki s'awati lede Ijesha; a o ni fi o s'awati laarin awon eniyan. Ulosiwaju (ilosiwaju), userere (iserere), ati ubukun(ibunkun) yio je tire.
W -Wa ri ba ti se, wa r'ona gbe gba.
Y - Yara ibukun, ire, ati ayo ailopin yoo ma ba e gbe titi ojo aye re......
AMIN (ASE N'TEDUMARE).

Courtesy: Rachel Toyin Odetayo (wall post) Read  with joy..... lobatan

Comments

Popular posts from this blog

Hundreds Arrested In Enugu Following Declaration Of Biafra Republic

Nollywood Star Tonto Dikeh for Big Brother?

Dele Momodu: This is another epistle to President Jonathan